Acts 4:32-35

Àwọn onígbàgbọ́ pín àwọn ohun ìní wọn

32 aÌjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. 33Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn. 34Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá. 35Wọ́n sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli, wọn sì ń pín fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe aláìní sí.

Copyright information for YorBMYO